BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Mọ̀lẹ́bí Omije oju mi fagilé ètò ìsìnkú tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ kéde
Ninu fidio kan to gun ori ayelujara lọjọ Aiku ni ẹnikan to pe ara rẹ ni Lanre Alewilese, toun naa jẹ akẹgbẹ Omije Oju mi, ti kede pe ẹbi Oloogbe naa ti fagile ikede iṣaaju, fun idi kan tabi ikeji.
Ilé ẹjọ́ gba béèlí Portable pẹ̀lú mílíọ́nù kan náírà àti onídúró méjì, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní kóòtù rèé
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ẹsun kan Portable, lara rẹ ni lilu awọn ọlọpaa ati ole jija.
Fídíò, Wasiu Ayinde K1 kò lẹ́tọ̀ọ́ sí àpèrè Awujale lọ́tẹ̀ yìí, Àwọn afọbajẹ ilẹ̀ Ijebu ṣàlàyé ìlànà tí wọ́n máa fi yan Awujale tuntun
Awọn afọbajẹ ni ilana aatẹẹle wa fun jijẹ Awujalẹ, ilana naa lawọn yoo si tẹlee.
'Ohun ìtìjú' - Ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú Senegal kúrò lórí pápá ìṣeré fún ìgbà díẹ̀ níbi ìdíje àṣekágbá Afcon 2025
Nígbà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà wọ ìṣẹ́jú méjìdínlọ́gọ́rùn-ún ni adarí eré, Jean Jacques Ndala lẹ́yìn àyẹ̀wò VAR fọn fèrè náà pé agbábọ́ọ̀lù tó ń gbá ọwọ́ ẹ̀yìn fún Senegal El Hadji Malick Diouf ṣe aṣemáṣe sí agbábọ́ọ̀lù Morocco, Brahim Diaz.
Destiny Boy, ọmọdé olórin tó kú lẹ́ni ọdún 22, ohun tí a mọ́ rèé
Bakan naa ni iroyin sọ pe oun nikan ṣoṣo naa ni ọmọ ti iya rẹ bi, baba rẹ lo bi awọn ọmọ miran.
Ìyá ló gbé bẹtiróòlù sí ṣọ́ọ̀bù ní Kwara tí iná fi jó ọmọ mẹ́ta pa-Iléeṣẹ panápaná
Nigba to n ṣalaye bi ina ọhun ṣe ṣẹyọ gan-an, Alukoro ileeṣẹ panapana Kwara sọ pe iwadii fi han pe obinrin kan to ni ọmọ mẹta lo ra epo bẹtiroolu to to lita aadọta (50 litres) to si gbe e pamọ sinu ṣọọbu tawọn ọmọ sun si.
NDLEA ti mú Kanmo-Kanmo,afurasí olóògùn olóró tí wọ́n ló pa òṣìṣẹ́ àjọ náà mẹ́ta lọ́dún méjìlá sẹ́yìn
Atẹjade ti Femi Babafemi, agbẹnusọ ajọ NDLEA, fi sita lọjọ Aiku oni, ṣalaye pe ogbologboo ni Kanmo-Kanmo ninu oogun oloro gbigbe lọ silẹ ibomiran, ati pe o pa mẹta lara awọn oṣiṣẹ NDLEA lọdun mejila sẹyin.
Ìyàn yóò mú ní Naijiria fún ìgbà àkọ́kọ́ láàárín ọdún mẹ́wàá – Àbọ̀ ìwádìí
Wọn sọ eyi ni ọjọ Ẹti, ti wọn si fikun pe gige ohun iranlọwọ lo jẹ ki eyi buru, ti ko si si aito ounjẹ kaakiri agbegbe naa.
Morocco ń retí àti gba ife ẹ̀yẹ AFCON lẹ́yìn àádọ́ta ọdún, Senegal ní yóò sọ bóyá yóò rí bẹ́ẹ̀ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ òní
Ifẹsẹwọnsẹ yii ti yoo waye ni olu ilu Morocco, Rabat (19:00 GMT) da ilẹ Afrika si ipin meji, nigbati orilẹede to dantọ ju ni apa ariwa Afrika, ti wọn wa ni ipo kọkanla ni agbaye yoo ma koju Senegal to jina si wọn wa ni iwọ oorun Afrika.
Mà á dupò gómìnà Oyo ní 2027 – Oriyomi Hamzat
Tẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni Hamzat ti n sọ pe oun yoo dupo gomina ipinlẹ Oyo, nitori awọn eeyan kan n polongo rẹ pe ipo naa tọ si i pupọ.
Ìwọ̀nyí ni àwọn ìpínlẹ̀ márùn ún tí ètò ààbò ti burú jùlọ ní Naijiria lọ́dún 2025
Lakọkọ, iha ariwa Naijiria lawọn iṣẹlẹ naa ti gbọngbọn julọ, amọ lonii, o fẹ ẹ dabi pe ko si agbegbe ti eto abo ti ṣẹnu ire ni Naijiria.
Jàndùkú pa obìnrin kan àti gbogbo ọmọ rẹ̀ mẹ́fà nínú ilé wọn ní Kano
Ọlọpaa sọ pe agbegbe Dorayi Chiranchi, niluu Kano ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ìtàn Mánigbàgbé: Baṣọ̀run Gáà jẹ́ àgbà ìjòyè tó le è yípadà sí ẹranko tó bá wù ú
Alaye ree lori ohun ti ọpọ ko mọ nipa itan Baṣọrun Gaa.
Ààrẹ Yoweri Museveni jáwé olúborí fún sáà kéje nínú ìdìbò Uganda
Museveni to ti wa nipo aarẹ lati odun 1986 n lọ fun saa keje bayii, yoo lo ọdun marun-un miran nipo naa gẹgẹ bi ofin orilẹede Uganda.
Seyi Makinde ṣèlérí mílíọ́nù márùn-ún náìrá fún ẹbí aṣọ́gbó kọ̀ọ̀kan tí agbébọn pa l'Oyo
Yatọ si owo naa, Makinde tun ṣeleri lati ran awọn ọmọ oku ọrun naa nile ẹkọ lati ipele alakọọbẹrẹ de Yunifasiti.
Lẹ́yìn ọdún márùndínlọ́gbọ̀n, ọmọ tí wọ́n bí sórí igi lásìkò ẹ̀kun omi jáde láyé
Ninu awọn olukẹdun naa sọ pe eto ilera ti kọ ṣe dede lorilẹede Mozambique wa lara nnkan to tete jẹ ko padanu ẹmi rẹ.
Imam tó dá ààbò bo àwọn Kristẹni sínú mọ́ṣáláṣí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn darandaran jáde láyé
Ní ọdún 2018 ni Imam Abubakar di gbajúgbajà káàkiri àgbáyé fún bí ó ṣe sá ààbò bo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó lé ní 200 lásìkò tí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà kan wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau lásìkò náà.
Àwọn ajínigbé mú àdínkù bá owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n ń bèèrè fún di N50m, ọ̀kadà mẹ́ta láti tu ọba tí wọ́n jígbé sílẹ̀
O salaye pe awọn ajinigbe naa sọ fun oun pe awọn ti din owo itusilẹ naa ku si aadọta miliọnu naira dipo ọgọrun-un kan miliọnu naira ti wọn n beere fun tẹlẹ.
Obìnrin tí àwọn dókítà gbàgbé sísọ́ọ̀sì sínú rẹ̀ lásìkò iṣẹ́ abẹ jáde láyé
Abubakar Mohammed, to jẹ ọkọ rẹ ṣalaye fun BBC pe fun ọpọ oṣu ni iyawo oun fi jẹ irora lẹyin iṣẹ abẹ ti wọn kọkọ ṣe fun ni Imam Urology Centre hospital, ni Kano.
Orílẹ̀èdè Niger gba ìwé àṣẹ padà lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ tó kọ̀ láti gbé epo lọ sí Mali nítorí ìkọlù agbésùnmọ̀mí
Tẹ o ba gbagbe, oṣu Kẹsan-an ni awọn ẹgbẹ alakatakiti kan ti wọn yapa lati ara al-Qaeda, gbegi dina gbigbe epo wọ Mali, ti wọn si n da awọn ọkọ epo lọna ni awọn ọna nla to jẹ marosẹ.
America so fífún Naijiria àti orílẹ̀èdè 74 míràn ní físà rọ̀ láì ní gbèdéke
Igbesẹ tuntun yii lo n waye lẹyin ọsẹ kan pere ti ijọba Aarẹ Trump kede owo asansilẹ (visa bond), to to $15,000 fun orilẹede mejidinlogoji to ba fẹ lọ si America, eyi ti Naijiria naa wa ninu wọn.
Àwọn aráàlú ló ń kún àwọn agbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́ láti máa da ìlú láàmú - Mínísítà ààbò
Musa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú BBC ṣàlàyé pé lára àwọn ohun èlò ìjà náà ló jẹ́ èyí tí ìjọba Nàìjíríà sanwó fún láti ọjọ́ pípẹ́, tí àwọn míì sì jẹ́ àjọṣepọ̀ orílẹ̀ èdè méjéèjì láti pọnkún ètò ààbò.
Ìjọba àpapọ àti ASUU tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tuntun tí yóò dènà ìyanṣẹ́lódì
Ọjọru ana ni wọn tọwọ bọwe adehun tuntun naa ni gbọngan TETFund, niluu Abuja.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé obìnrin mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Oyo
Nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn afurasi ajinigbe yii jẹwọ wipe otitọ lawọn jẹbi ọrọ naa, amọ ere lawọn n ṣe.
Ìròyìn Pàtàkì
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Awuyewuye bí ọmọ Atiku Abubakar ṣe darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, kéde àtìlẹyìn fún Tinubu
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kìíní ni igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Barau Jibrin àti igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́kùn ìlà oòrùn àríwá Mallam Mustapha Saliu gba Abba Atiku Abubakar sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìlú Abuja.
Gómìnà Seyi Makinde kéde Olubadan bíi alága lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo, Aláàfin fọnmú
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti kéde Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja gẹ́gẹ́ alága àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Oyo àmọ́ Aláàfin ní òun kò faramọ.
Mò ń wá ọkọ, mo ti ṣetán láti fàyè gba ìfẹ́ nínu ọkàn mi – Princess Damilola
Princess lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ nibi to ti rawọ ẹbẹ si awọn gbajumọ pasitọ ni Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ lati mu afojusun ọhun ṣẹ.
Àlàyé lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo tó sọ akẹ́kọ̀ọ́ àti èèyàn 52 dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n
Ẹgbẹ awọ akẹkọọ, NANS sọ pe iwa ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo n wu si awọn akẹkọọ naa ko tọ o si jẹ titẹ etọ araalu loju mọlẹ.
Gbas-gbos ní ìpínlẹ̀ Rivers àti àtunbọ̀tán òṣèlú bàbá ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà
Wo awọn ipinlẹ ti ija ti waye laarin gomina ati baba isalẹ rẹ, eyii to da rogbodiyan silẹ laarin ilu.
Tinubu, Obasanjo, Sanwo-Olu àtàwọn mí-ìn ń ṣèdárò Ọba Akran tó wàjà ní Badagry
Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Aje ni iroyin ipapoda àgbà ọba fun gbogbo Badagry naa gbode. Ẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89) ni Kabiyesi naa ki ọlọjọ too de.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọkùnrin tó 'gún ìyàwó rẹ̀ pa' tóun náà sì pa ara rẹ̀ l'Ogun
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fesi lori iṣẹlẹ naa tẹlẹ, iyalẹnu lo ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to n gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun.
''Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti wà lójúfò fáwọn agbébọn tó ṣèlérí láti ṣèkọlù sí Ikoyi-Ile l'Ogbomoso''
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Benjamin HUndeyin, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.








































































